Ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n (28), Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

ÀLÀYÉ ÌWÉ GALATIA L’ẸSẸẸSẸ (3)

Nínú Episteli sí àwọn Galatia yìí ni Paulu ti sọ nípa ohun tó ṣẹlẹ láàrin ohun ati Pétérù dé ibi wípé nígbà tí
Pétérù n ṣe agabagebe, Paulu ní láti sọrọ síi ní gbangba.


GALATIA 2:11-14
[11]Ṣugbọn nigbati Peteru wá si Antioku, mo ta kò o li oju ara rẹ̀, nitoriti o jẹ ẹniti a ba bawi.
[12]Nitoripe ki awọn kan ti o ti ọdọ Jakọbu wá to de, o ti mba awọn Keferi jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn de, o fà
sẹhin, o si yà ara rẹ̀si apakan, o mbẹ̀ru awọn ti iṣe onila.
[13]Awọn Ju ti o kù si jùmọ ṣe agabagebe bẹ̃gẹgẹ pẹlu rẹ̀; tobẹ̃ti nwọn si fi agabagebe wọn fà Barnaba
tikararẹ lọ.
[14]Ṣugbọn nigbati mo ri pe nwọn kò rìn dẽdẽ gẹgẹ bi otitọ ihinrere, mo wi fun Peteru niwaju gbogbo wọn
pe, Bi iwọ, ti iṣe Ju, ba nrìn gẹgẹ bi ìwa awọn Keferi, laiṣe bi awọn Ju, ẽṣe ti iwọ fi nfi agbara mu awọn Keferi
lati mã rìn bi awọn Ju?


Paulu sọ wípé Peteru kò rìn déédé bí òtítọ ihinrere ti Kristi, bẹẹ Pétérù kò bàa jiyàn wipe kò rí bẹ́ẹ̀nitoripe
òtítọ ni nkan tí Paulu n sọ. Òtítọ ni ihinrere Kristi ni wipe Ọlọrun ti tẹwọgba gbogbo ènìyàn kò sì fi iyatọ sí
àárín Júù tàbí aláikola. Peteru, pàápàá jùlọ yẹ kó mọ èyí nitoripe nipasẹ iṣẹ iransẹ rẹ ni Jésù fi tẹwọgba awọn
ará ilé Korneliu, alaikọlà. Ṣugbọn ohun tí a fẹ mú jáde láti inú àlàyé yìí ni wipe bí Paulu ṣe ní ìgboyà láti bá
Pétérù wí àti wípé ìbáwí náà kò fa ìjà jẹ kí a mọ nípa ọ̀wọ̀tí wọn fi wọ Paulu láàrin àwùjọ àwọn Aposteli


Àmin míràn tí a tún máa n wò mọ awọn Aposteli lára ni boya awọn àmin tí Jésù sọ wípé yóò máa tẹlé awọn
ọmọlẹyìn rẹ n jẹyọ nínú ayé wọn.


MAKU 16:17-18
[17]Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ́lọ; Li orukọ mi ni nwọn o ma lé awọn ẹmi èṣu jade; nwọn o si
ma fi ède titun sọ̀rọ;
[18]Nwọn o si ma gbé ejò lọwọ; bi nwọn ba si mu ohunkohun ti o li oró, kì yio pa wọn lara rara: nwọn o gbé
ọwọ́le awọn ọlọkunrun, ara wọn ó da.

JOHANU 14:12
[12]Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, iṣẹ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi jù wọnyi
lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.


Nínú ìwé Ìṣe Àwọn Aposteli, a ri wipe awọn àmin náà jẹyọ lọpọlọpọ nínú ayé àwọn Aposteli. Bẹẹ náà ni èyí rí
nínú ayé Paulu Aposteli. Àmin


KỌRINTI KEJI 12:12
[12]Nitõtọ a ti ṣe iṣẹ àmi Aposteli larin nyin ninu sũru gbogbo, ninu iṣẹ àmi, ati iṣẹ iyanu, ati iṣẹ agbara.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading