Ọjọ́ Keje(8), Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(8)

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(8)


Awọn ibi tó tí yẹ kí a kiyesara wà nínú aawẹ̀gẹgẹ bí onigbagbọ. Lootọ fún ọjọ mélòó sẹhin ni a ti n sọrọ nípa
àwọn ànfààní tó wà nínú aawẹ̀ati ádùrá. Ìgbà míràn wà tí ẹlòmíràn máa fojú wo aawẹ̀gẹgẹ bíi ajebiidan, kò
rí béè. Gẹgẹ bí a ti salaye télètélè, bóyá a gba aawẹ̀tàbí a kò gba aawẹ̀kò ní ohunkóhun ṣe pẹlu ifẹ Ọlọrun
fún wa nínú ádùrá. Jésù ṣe ìlérí ìdáhùn ádùrá fún wa laiṣe wipe o sọ fún wa wípé àyàfi dandan kí a gbàdúrà kí
a tó lè rí ìdáhùn.


Awọn kan máa n gba aawẹ̀tó tí gùn jù. Ẹlòmíràn máa n tọkasi aawe ogójì ọsán ati ogoji oru tí Jésù gbà. Lootọ
Jésù gba aawẹ̀ogójì ọsán àti ogójì oru ṣugbọn kò sí ibi kánkan tó ti sọ wípé kí a wo èyí bí awokọṣe, kí awa
náà sì gba aawẹ̀ogójì ọsán ati ogoji oru. Njẹ a sakiyesi wipe Jésù tó ṣe èyí gan ṣe bẹẹ nítorí pé o gba ìdarí Èmi
Mimọ láti ṣe bẹẹ ni?


MATIU 4:1-2
[1]NIGBANA li a dari Jesu si ijù lati ọwọ́Ẹmi lati dán a wò lọwọ Èṣu.
[2]Nigbati o si ti gbàwẹ li ogoji ọsán ati ogoji oru, lẹhinna ni ebi npa a.


Njẹ a n sọ wípé àyàfi tí a bá gba ìdarí Èmi Mimọ kí a tó lè gba aawẹ̀ni? Rárá. Jésù retí wipe àwa omolehin rẹ
yóò máa gba aawẹ̀lóòrèkóòrè sugbon kò pọn ni dandan láti gba aawẹ̀ọlọjọ pipẹ.

MATIU 6:16
[16]Ati pẹlu nigbati ẹnyin ba ngbàwẹ, ẹ máṣe dabi awọn agabagebe ti nfajuro; nwọn a ba oju jẹ, nitori ki
nwọn ki o ba le farahàn fun enia pe nwọn ngbàwẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na.


Bí Jésù ṣe sọ wípé “nigbati” túmọ sí pé ohun tó retí wipe a o maa ṣe ni. Nitorinà kìíse dandan kí a máa dúró
dé ìdarí kánkan láti gba aawẹ̀ṣugbọn a gbọdọ ṣeé ni iwontunwonsi.
Ẹlòmíràn tó gba aawẹ̀ogójì ọjọ nínú Bíbélì wà nínú ògo Ọlọrun ní gbogbo ọjọ náà, nítorínaa kò nilo láti Jẹun.
Orúkọ rẹ ni Mose.


ẸKISODU 34:28
[28]On si wà nibẹ̀, lọdọ OLUWA li ogoji ọsán ati ogoji oru: on kò jẹ onjẹ, bẹni kò mu omi. On si kọwe ̃ ọ̀rọ
majẹmu na, ofin mẹwa nì, sara walã wọnni.


Nitoripe o wà lábé ogo Ọlọrun, a kò le lo èyí gẹgẹbi àpẹẹrẹ aawẹ̀gbigba nitoripe kìíse gbogbo ìgbà ni èyí n
ṣẹlẹ sí gbogbo onigbagbọ. A gbọdọ rí wípé a kò fi ìlera ara wa we ẹwù nípa àwọn ìwà tó léwu, aawẹ̀ọlọjọ
pipẹ gẹgẹ bí àpẹẹrẹ. Ìgbà míràn wà tí ẹlòmíràn máa n ro wipe aawẹ̀tí wọn gbà ni ìdí tí ọlọrun yóò fi gbọ
ádùrá wọn. Kò rí bẹ́ẹ̀, yálà Jésù pe èyí ní òdodo ara ẹni, o sọ fún wa láti yẹra fún irú ìwà bẹẹ.

MATIU 6:16-18
[16]Ati pẹlu nigbati ẹnyin ba ngbàwẹ, ẹ máṣe dabi awọn agabagebe ti nfajuro; nwọn a ba oju jẹ, nitori ki
nwọn ki o ba le farahàn fun enia pe nwọn ngbàwẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. d.
[17]Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbàwẹ, fi oróro kùn ori rẹ, ki o si bọju rẹ;
[18]Ki iwọ ki o máṣe farahàn fun enia pe iwọ ngbàwẹ, bikoṣe fun Baba rẹ ti o mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si
riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading