Ọjọ́ Keje(7), Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(7)

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(7)


Tí a bá n wa ojú Olúwa fún nkan kan pàtó, aawẹ̀wà lára nkan tí a lè ṣe. Ẹ jẹ ki a mọ wipe kìíse wípé tí a kò bá
gba aawẹ̀Ọlọrun kò níí gbọ. Kò sí ẹsẹ Bíbélì kánkan to sọ fún wa bẹẹ wipe àyàfi tí a bá fi aawẹ̀gbe ádùrá wa
lowo wípé Ọlọrun kò níí gbọ. Idahun ádùrá niiṣe pẹlu ìlérí Ọlọrun. Ọpọlọpọ ìlérí Ọlọrun ni a lè tọkasi tó fi dá
wa lójú wípé lóòtó Ọlọrun máa n gbọ ádùrá.


MATIU 7:7-8
[7]Bère, a o si fifun nyin; wá kiri, ẹnyin o si ri; kànkun, a o si ṣí I silẹ fun nyin.
[8]Nitori ẹnikẹni ti o bère nri gbà; ẹniti o ba si wá kiri nri: ẹniti o ba si nkànkun, li a o ṣí I silẹ fun.


JOHANU 14:14
[14]Bi ẹnyin ba bère ohunkohun li orukọ mi, emi ó ṣe e.

JOHANU KINNI 5:14
[14]Eyi si ni igboiya ti awa ni niwaju rẹ̀, pe bi awa ba bère ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, o ngbọ ti wa:


Nítorínaa bóyá a gba aawẹ̀tàbí a kò gba aawẹ̀, Olododo ni Ọlọrun láti dahun ibeere wa. Gẹgẹ bí a ti sọ nínú
ẹkọ yìí wipe ipa tí aawẹ̀n kò kìíse lórí Ọlọrun bikòṣe lórí ọkàn ènìyàn. Nitorinà láti lè mú ọkàn wa ṣe pípé
nínú ádùrá pẹlu Ọlọrun, kí ọkàn wa wà nínú ìfẹ rẹ, a lè lo aawẹ̀fún èyí. Èyí ló fàá tí a fi rí ọpọlọpọ awọn
eniyan nínú Bíbélì tí wọn n wa ojú Ọlọrun pẹlu aawẹ̀.
Nítorí ohun tí Dafidi n fẹ láti ọdọ Ọlọrun, O gba aawẹ̀

SAMUẸLI KEJI 12:15-16
[15]Natani si lọ si ile rẹ̀. Oluwa si fi arùn kọlù ọmọ na ti obinrin Uria bi fun Dafidi, o si ṣe aisàn pupọ.
[16]Dafidi si bẹ̀Ọlọrun nitori ọmọ na, Dafidi si gbàwẹ, o si wọ inu ile lọ, o si dubulẹ lori ilẹ li oru na.


Bẹẹ náà ni Esira


ẸSIRA 8:21-23
[21]Nigbana ni mo kede àwẹ kan nibẹ lẹba odò Ahafa, ki awa ki o le pọn ara wa loju niwaju Ọlọrun wa, lati
ṣafẹri ọ̀na titọ́fun wa li ọwọ rẹ̀, ati fun ọmọ wẹrẹ wa, ati fun gbogbo ini wa.
[22]Nitoripe, oju tì mi lati bère ẹgbẹ ọmọ-ogun li ọwọ ọba, ati ẹlẹṣin, lati ṣọ wa nitori awọn ọta li ọ̀na: awa sa
ti sọ fun ọba pe, Ọwọ Ọlọrun wa mbẹ lara awọn ti nṣe afẹri rẹ̀fun rere; ṣugbọn agbara rẹ̀ati ibinu rẹ̀mbẹ
lara gbogbo awọn ti o kọ̀ọ silẹ.
[23]Bẹli awa gbàwẹ, ti awa si b ̃ ẹ̀Ọlọrun wa nitori eyi: on si gbọ́ẹ̀bẹ wa.
Njẹ a rí èsì aawẹ̀ati ádùrá wọn ti Ọlọrun gbọ ẹ̀bẹ̀wọn.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading