Ọjọ́ Keje(7), Ọjọ́ Ìsẹ́gun , Oṣù Kejì , Ọdún 2023

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (7)

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (7)


Awọn nkan tí a kà sílẹ gẹgẹ bí àwọn ohun àmúyẹ lati ṣe iṣẹ iransẹ fihàn wípe ìhùwàsí onigbagbọ ṣe pàtàkì fún
iṣẹ iransẹ. Kò sí ẹnikẹni tí Ọlọrun kìí yẹwo kò tó gbé iṣẹ iransẹ le wọn lọwọ. A nilo àkókò láti rí ihuwasi tòótọ
tó wà nínú ayé ènìyàn nítorípé agabagebe pọ káàkiri. Kìíse wipe wọn kìíse onigbagbọ ṣugbọn ìgbà míràn wà
tó jẹ wipe awọn ìwà búburú tí kò yẹ fún iṣẹ iransẹ máa n farahàn nínú ayé ọpọlọpọ, èyí sì lè ṣe ìdènà fún iṣẹ
iransẹ.


Láti ibẹrẹ nínú ìwé Ìṣe Awọn Aposteli ni wọn tí máa n sọ nípa wipe awọn tí wọn bá fẹ láti yan sínú iṣẹ iransẹ
gbọdọ jẹ awọn ti ijọ Ọlọrun ti ni anfaani láti rí ihuwasi awọn ẹni náà.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 6:3
[3]Nitorina, ará, ẹ wo ọkunrin meje ninu nyin, olorukọ rere, ẹniti o kún fun Ẹmí Mimọ́ati fun ọgbọ́n, ẹniti
awa iba yàn si iṣẹ yi.


Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, a rí àwọn ohun àmúyẹ tí àwọn Aposteli gbé kalẹ fún ẹnikẹni ti a o bá yan lati ṣe iṣẹ
Ọlọrun. Ẹ jẹ kí a ṣakiyesi iṣẹ tí wọn fẹ yan awọn ènìyàn sí, kìíse iṣẹ Efanjelisti, tàbí oluso-aguntan tàbí Olukọni
bikòṣe iṣẹ awọn Diakoni tí yóò máa ṣètò ounjẹ pínpín láàárín àwọn ènìyàn nínú ìjọ Ọlọrun.
Sibẹsibẹ a ri wipe awọn ohun àmúyẹ nípa ti Èmi ṣe pàtàkì fún wọn. Èyí ló n sọ fún wa wipe láti jẹ ẹni tí o yege
nínú iṣẹ Ọlọrun, ayé wa gbọdọ bá awọn ohun àmúyẹ náà mu. Láti lè mọ wipe Ọlọrun ní ìtara láti lò wá, ẹ gbọ
ohun tí Kristi funrararẹ wí .


LUKU 19:40
[40]O si da wọn lohùn, o wi fun wọn pe, Mo wi fun nyin, Bi awọn wọnyi ba pa ẹnu wọn mọ́, awọn okuta yio
kigbe soke.

Èyí n sọ fún wa wípé àwon ohun àmúyẹ náà kìíse wipe Oorun ló n fi ìdènà sí wa l’ọna láti má lè ṣìṣe rẹ,
ohunkóhun tó bá fi ara rẹ silẹ tàbí ẹnikẹ́ni tó bá jọwọ ara rẹ ni Ọlọrun yóò lo. Sugbọn tí Ọlọrun bá n lo wá, a
fẹ jẹ ohun èlò tó yege, a fẹ ṣe àṣeyọrí nínú iṣẹ iransẹ. Ìdí èyí ló fi ṣe pàtàkì kí a ṣeé bí Ọlọrun ṣe ní lọkàn. Yatọ
sí lẹta Paulu sí Timotiu nípa àwọn ohun àmúyẹ fún iransẹ Ọlọrun, Jésù náà sọ nípa àwọn ifara-eni-jin fún
ẹnikẹni tó bá fẹ ṣiṣe iransẹ bíi tirẹ.


MATIU 16:24
[24]Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati tọ̀mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé
agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀mi lẹhin.


O ní irú ifara-eni-jin tí yóò ná wa tí a bá fẹ ṣiṣe iransẹ pẹlu ọkàn tó t’ọna
Awọn iṣẹ ti ara wà tí a gbọdọ ṣe nkan kan nípa wọn ki wọn má baà di wa lọwọ.


TIMOTI KINNI 3:2-4
[2]Njẹ biṣopu jẹ alailẹgan, ọkọ aya kan, oluṣọra, alairekọja, oniwa yiyẹ, olufẹ alejò ṣiṣe, ẹniti o le ṣe olukọ.
[3]Ki o má jẹ ọmuti, tabi onijà, tabi olojukokoro, bikoṣe onisũru, ki o má jẹ onija, tabi olufẹ owo;
[4]Ẹniti o kawọ ile ara rẹ̀girigiri, ti o mu awọn ọmọ rẹ̀tẹriba pẹlu ìwa àgba gbogbo;

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading