Ọjọ Kẹfà (6), Ọjọ́Ẹtì , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(6)

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(6)


Nkan miran tí aawẹ̀àti ádùrá n ṣe nínú ayé onigbagbọ ni wípé o máa n ràn ọkan wa láti sipaya sí Ọlọrun, láti
gba itoni tàbí ìdarí. Ní ọjọ meji sehin ni a ti n sọ wípé aawẹ̀niiṣe pẹlu okan onigbagbọ. Bẹẹ náà ni ìdarí èmi
Ọlọrun ri. Tí a bá n wá ojú Ọlọrun fun nkan kan pàtó, a lè fi aawẹ̀ran ara wa lọwọ nitoripe aawẹ̀máa n jẹ kí a
dojukọ ádùrá nínú idapọ pẹlu Ọlọrun lai ro nkan míràn.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 13:2
[2]Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀fun mi fun
iṣẹ ti mo ti pè wọn si.


Njẹ a sakiyesi nkan tí wọn n ṣe nígbàtí Èmi Mimọ bá wọn sọrọ? Wọn n gba aawẹ̀ati ádùrá nígbà tí wọn gbọ
láti ọdọ Èmi Mimọ. Nítorínaa, aawẹ̀àti ádùrá máa n ran wá lọwọ láti ní isipaya. Lẹhin aawẹ̀náà ni àwọn
angẹli wá n ṣe iransẹ fún Jésù náà.


MATIU 4:2,11
[2]Nigbati o si ti gbàwẹ li ogoji ọsán ati ogoji oru, lẹhinna ni ebi npa a.
[11]Nigbana li Èṣu fi I silẹ lọ; si kiyesi I, awọn angẹli tọ̀ọ wá, nwọn si nṣe iranṣẹ fun u.

Èyí ṣe pàtàkì, pàápàá jùlọ fún àwọn iransẹ Ọlọrun tó fẹ tẹlé Itoni Ọlọrun nínú iṣẹ iransẹ. A ní láti fi ara wa jì
fún aawẹ̀àti ádùrá. Gẹgẹ bí ọrọ náà tí jẹ, “ise iransẹ “ èyí ni wípé oníwàásù ọrọ Ọlọrun n jẹ iṣẹ ti a ran ni.
Nitorinà, a gbọdọ gbọ láti ọdọ Ọlọrun nípa iṣẹ tó fẹ rán wa.


Pàápàá jùlọ tí a bá fẹ bẹrẹ nkan kan pàtó nínú iṣẹ iransẹ aawẹ̀àti ádùrá ṣe pàtàkì. Itoni Èmi Mimọ ni
oníwàásù tàbí ọmọ Ọlọrun fi máa n mọ ibi tó yẹ kí a yà sí nípa ti iṣẹ iransẹ.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 14:23
[23]Nigbati nwọn si ti yàn awọn àgbagba fun olukuluku ijọ, ti nwọn si ti fi àwẹ gbadura, nwọn fi wọn le
Oluwa lọwọ, ẹniti nwọn gbagbọ́.


A o ri wipe kí wọn tó ran àwọn iransẹ náà jáde, kí wọn tó yan awọn ènìyàn sínú iṣẹ iransẹ, wọn gba aawẹ̀àti
ádùrá


Nitoripe ìdarí ṣe pàtàkì fún onigbagbọ, ìgbà míràn tí a bá gbọ nkan kan láti ọdọ Ọlọrun, o yẹ kí o dá wa lójú
daradara

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading