Ọjọ́ Kẹfà (6), Ọjọ́ Ajé , Oṣù Kejì , Ọdún 2023

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (6)

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (6)


Lẹẹkansi kìíse ènìyàn ló n pè wá sínú iṣẹ iransẹ. Ọlọrun ló n pe onigbagbọ sínú iṣẹ iransẹ ṣugbọn ènìyàn ni
Ọlọrun máa n lò láti ṣe ìfilọ́lẹ̀àti ìfimuleẹ̀ipe tí Ọlọrun ti pè wá sí. Ìgbà míràn wà tó jẹ wípé iransẹ Ọlọrun tí a
kò bọwọ fún bí o ṣe yẹ gan ni Ọlọrun yóò lo láti sọ nípa ipè wa. Èyí ṣẹlẹ nígbàtí Samueli gba ìpè nípa iṣẹ
iransẹ.


Eli dà bí Àlùfáà tí ìdájọ Ọlọrun ti wà lórí ìdílé rẹ ni, gbogbo ènìyàn mọ nípa èyí. Nitorina Samueli wà labẹ
ìdánwò láti má tẹriba fún wòlíì náà.


SAMUẸLI KINNI 2:22,35
[22]Eli si di arugbo gidigidi, o si gbọ́gbogbo eyi ti awọn ọmọ rẹ̀ṣe si gbogbo Israeli; ati bi nwọn ti ima ba
awọn obinrin sùn, ti nwọn ma pejọ li ẹnu ọ̀na agọ ajọ.
[35]Emi o gbe alufa olododo kan dide, ẹniti yio ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu mi, ati ọkàn mi; emi o si kọ ile kan ti yio
duro ṣinṣin fun u; yio si ma rin niwaju ẹni-ororo mi li ọjọ gbogbo.


Samueli iba ti tọkasi Alufaa yìí wipe bóyá eleyii kò tilè mọ nkankan nípa bí Ọlọrun ṣe máa n bá ènìyàn sọrọ
tàbí nípa iṣẹ iransẹ. Kò ṣe bẹẹ, nígbà tó gbọ ipè Ọlọrun, Àlùfáà tí ìdájọ Ọlọrun ti wà lórí rẹ yi náà ló sọ ohun tí
yóò ṣe fún.


SAMUẸLI KINNI 3:9
[9]Nitorina Eli wi fun Samueli pe, Lọ dubulẹ: yio si ṣe, bi o ba pè ọ, ki iwọ si wipe, ma wi, Oluwa; nitoriti
iranṣẹ rẹ ngbọ́. Bẹ̃ni Samueli lọ, o si dubulẹ nipò tirẹ̀.


Kìíse ojúṣe wa láti dá iransẹ Ọlọrun kánkan lẹjọ nítorípé kìíse àwa ni a pè wọn sí inú iṣẹ iransẹ. Nítorínaa a
gbọdọ noni iṣẹ iransẹ wọn nitoripe o lè jẹ wípé àwon ni Ọlọrun yóò lo fún wa.

Tí àwa bá jẹ iransẹ Ọlọrun, tí a sì ní ojúṣe láti ṣe igbọwọlè fún àwọn ènìyàn kan tàbí òmíràn fún iṣẹ iransẹ. Ẹ
jẹ kí a mọ wipe “Oluwa sọ fún mi pé báyìí báyìí “ kò tó. Ó ní àwọn ìlànà tí Bíbélì fi le’lẹ nípa èyí.


TIMOTI KINNI 5:22
[22]Máṣe fi ikanju gbe ọwọ́le ẹnikẹni, bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ alabapin ninu ẹ̀ṣẹ̀awọn ẹlomiran: pa ara rẹ mọ́ni
ìwa funfun.


A kò gbọdọ kánjú láti pe awon eniyan sínú iṣẹ iransẹ tàbí láti fi wọn ṣe alàgbà, Diakoni tàbí Olusoaguntan.
Ìgbà míràn wà tí àwọn iransẹ Ọlọrun míràn máa n fi awọn tí a kò tíì farabale kọ ní ọrọ Ọlọrun jẹ oyè kan tàbí
òmíràn kí wọn má baà kúrò nínú ìjọ tàbí nítorí anfààní kan tàbí òmíràn tí ìjọ n jẹ lára ẹni bẹẹ. Ìwà pálapàla
nínú iṣẹ iransẹ ni èyí b kò t’ọna rárá ati rárá. Tí a bá wo bí wọn ṣe n yan awọn ènìyàn sí iṣẹ Ọlọrun nínú Bíbélì,


O ní í ìdí tí ohun àmúyẹ fi wà nínú àkọsílẹ.


TIMOTI KINNI 3:1-4
[1]OTITỌ ni ọ̀rọ na, bi ẹnikan ba fẹ oyè biṣopu, iṣẹ rere li o nfẹ. [2]Njẹ biṣopu jẹ alailẹgan, ọkọ aya kan,
oluṣọra, alairekọja, oniwa yiyẹ, olufẹ alejò ṣiṣe, ẹniti o le ṣe olukọ. [3]Ki o má jẹ ọmuti, tabi onijà, tabi
olojukokoro, bikoṣe onisũru, ki o má jẹ onija, tabi olufẹ owo;
[4]Ẹniti o kawọ ile ara rẹ̀girigiri, ti o mu awọn ọmọ rẹ̀tẹriba pẹlu ìwa àgba gbogbo;

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading