Ọjọ́ Karùndínlógún (15), Ọjọ́rú , Osù Kejì , Ọdún 2023

KRISTẸNI GẸGẸ BÍ IMỌLẸ (8)

Ìdáhùn tí Jésù fún ìbéèrè ti wọn béèrè lọwọ rẹ nípa òfin tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú Gbogbo òfin ni a fẹ gbé yẹwo lónìí.

MATIU 22:36-40
[36]Olukọni, ewo li aṣẹ nla ninu ofin?
[37]Jesu si wi fun u pe, Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ́ Ọlọrun Oluwa rẹ.
[38]Eyi li ekini ati ofin nla.
[39]Ekeji si dabi rẹ̀, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.
[40]Ninu awọn ofin mejeji yi ni gbogbo ofin ati wolĩ rọ̀ mọ́.

A lè rò wípé òfin tí Jésù n fún àwa onigbagbọ ni èyí. Kò rí bẹẹ́ ̀ ràrá. Ẹ jẹ kí a kọkọ mọ wipe Júù ni ẹni tó wá sọdọ Jésù. Jésù sì n dahùn gẹgẹ bí olukọni labẹ òfin Mósè ni fún ẹni náà. Ìdí èyí ni ẹni náà ṣe péé ní Rabbi, Olukọni. Awọn tó ṣe ẹkọ labẹ òfin Mósè ni wọn máa n pè ní Olukọni. Nítorínaa o dahùn gẹgẹ bíi ìtùmò ohun tí Mósè kọ sílẹ ni. Ẹnikẹni tí kò bá wà labẹ òfin Mósè kò ní ojúṣe láti ṣe atẹle òfin náà nitoripe kìíse gbogbo ènìyàn ló wà labẹ ofin náà.

ROMU 2:12
[12]Nitori iye awọn ti o ṣẹ̀ li ailofin, nwọn ó si ṣegbé lailofin: ati iye awọn ti o ṣẹ̀ labẹ ofin, awọn li a o fi ofin dalẹjọ;

Onigbagbọ kò sí labẹ òfin Mósè.

ROMU 10:4
[4]Nitori Kristi li opin ofin si ododo fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́.

Bíbélì pe Kristi ní òpin òfin.

GALATIA 3:24
[24]Nitorina ofin ti jẹ olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbọ́.

Lẹhin ìgba ti Kristi ti dé ní báyìí, kò sí ẹnikẹ́ni tó wà labẹ òfin mọ. Njẹ èyí túmọ̀sí wípé a kò ní ojúṣe láti rìn nínú ìfẹ nitoripe o wà nínú òfin Mósè ni? Rárá àti rárá. Jésù náà ní òfin tirẹ. Ẹ gbọ ohun ti Jésù sọ

JOHANU 14:15
[15]Bi ẹnyin ba fẹran mi, ẹ ó pa ofin mi mọ́.

Èyí ni wipe Jésù náà ní òfin tirẹ tó yàtọ sí òfin Mósè. Kíni òfin Jésù, òfin titun, tí Jésù fún wa? Tó bá di ọla a o máa sàlàyé èyí.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading