Ọjọ́ Karundinlọ́gbọ̀n (25), Ọjọ́rú , Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

ṢÍṢE IṢẸ OLÚWA (7)

Ohun tó n jẹ wípé iná Emi n jo nínú ayé onigbagbọ ni wipe o ní ìtara fún iṣẹ Ọlọrun. Ara amin wípé
onigbagbọ nínú Kristi Jésù n dagbasoke síi nínú ìgbàgbọ ni èyí. Onigbagbọ ti kò bá mú ìwàásù Kristi ni ọna tó
ṣe pàtàkì kò dagbasoke.


EFESU 4:11-12
[11]O si ti fi awọn kan funni bi aposteli; ati awọn miran bi woli; ati awọn miran bi efangelisti, ati awọn miran
bi oluṣọ-agutan ati olukọni;
[12]Fun aṣepé awọn enia mimọ́fun iṣẹ-iranṣẹ, fun imudagba ara Kristi:


Ohun tí asepe túmọ̀sí nínú abala Bíbélì tí a n tọkasi yìí náà ni idagbasoke. Ìdùnnú Ọlọrun ni gẹgẹ bí Baba wa
nípa ti Ẹmi wípé a o máa dagbasoke síi. Kí ènìyàn mọ ojúṣe rẹ kó sì ṣe bẹẹ ni àmin wipe iru ẹni bẹẹ n
dagbasoke síi. Bẹẹ náà ló rí nípa ti Ẹmi. Idagbasoke nipa ti Ẹmi ni wipe onigbagbọ mọ ojúṣe rẹ nínú ara Kristi
O sì n ṣe bẹẹ gẹgẹ. Ìwàásù Kristi fún àwọn ènìyàn ni ojúṣe wa.
Nínú mọlẹbi Ọlọrun ni a wà gẹgẹ bí onigbagbọ.


EFESU 3:14-15
[14]Nitori idi eyi ni mo ṣe nfi ẽkun mi kunlẹ fun Baba Oluwa wa Jesu Kristi,
[15]Orukọ ẹniti a fi npè gbogbo idile ti mbẹ li ọrun ati li aiye,


HEBERU 12:9
[9]Pẹlupẹlu awa ni baba wa nipa ti ara ti o ntọ́wa, awa si mbù ọlá fun wọn: awa kì yio kuku tẹriba fun Baba
awọn ẹmí ki a si yè?


Ọlọrun ni Baba Emi wa nínú mọlẹbi yìí. Ọlọrun ní ojúṣe lórí wa, o sì jẹ olódodo sí ojúṣe rẹ. Bẹẹ náà ló yẹ kí
àwa náà ri. A gbọdọ mọ ojúṣe wa nínú mọlẹbi náà kí a sì ṣe bẹẹ gẹgẹ. Ojúṣe wa nínú mọlẹbi Ọlọrun ni ìwàásù
ihinrere Kristi fún àwọn ènìyàn. Ọlọrun kìí wàásù, àwa ló gbé iṣẹ náà le lọwọ. Tó bá jẹ wípé Ọlọrun ló máa n
wàásù ìhìnrere rẹ fúnra rẹ ni, a ti yìí gbogbo ènìyàn lọkàn padà lẹẹkan soso.

MATIU 9:37-38
[37]Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀pe, Lõtọ ni ikorè pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nkan;
[38]Nitorina ẹ gbadura si Oluwa ikorè ki o le rán awọn alagbaṣe sinu ikorè rẹ̀.


Jésù pe àkíyèsí wa sí ìkórè tó pọ ṣugbọn kò sọ wipe Baba yóò sọ ara rẹ di alagbaṣe. Ènìyàn ni alagbaṣe, laiṣe
wipe a wàásù ìhìnrere, awọn ènìyàn yóò ṣegbe. Tí a bá n fojú eyi wo Ise iransẹ, a kò ní nilo ìwúrí láti ọdọ
ẹnikan kí a tó la ẹnu wa láti sọrọ nipa Kristi fún àwọn ènìyàn.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading