Ọjọ́ Kàrún (5), Ọjọ́bọ̀, Oṣù ́Kíní , Ọdún 2023

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(5)

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(5)


Okan nínú anfààní to wà nínú aawẹ̀gbígba pàápàá jùlọ tí ènìyàn bá n ronupiwada ni wípé O máa n ràn wá
lọwọ láti ní ẹrí ọkàn rere níwájú Olúwa. Ę jẹ kí a mọ wipe Ọlọrun rí ọkan wa


SAMUẸLI KINNI 16:7
[7]Ṣugbọn Oluwa wi fun Samueli pe, máṣe wo oju rẹ̀, tabi giga rẹ̀; nitoripe emi kọ̀ọ: nitoriti Oluwa kì iwò bi
enia ti nwò; enia a ma wò oju, Oluwa a ma wò ọkàn.


Ọkan wa ni Ọlọrun máa n wò. Nitorinaa tí ènìyàn bá gba aawẹ̀ninu ironupiwada kìíse wipe a fẹ fi ipò tí ọkàn
wa wà dá Ọlọrun lójú. Ara wa ni a n fi dá lójú nítorípé bóyá a gba aawẹ̀tabi a kò gba aawẹ̀Ọlọrun mọ
èròngbà ọkan wa. Akiyesi pataki wà tó yẹ kí a tọkasi nínú ìdáhùn Jésù sí àwọn ọmọlẹyìn rẹ.


MATIU 17:20-21
[20]Jesu si wi fun wọn pe, Nitori aigbagbọ́nyin ni: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́bi wóro
irúgbin mustardi, ẹnyin o wi fun òke yi pe, Ṣi nihin lọ si ọ̀hun, yio si ṣi; kò si si nkan ti ẹ ki yio le ṣe.
[21]Ṣugbọn irú eyi ki ijade lọ bikoṣe nipa adura ati àwẹ̀.

Nínú ẹsẹ ogún, Jésù sọ ohun tó jẹ ìṣòro wọn , O sọ wipe aigbagbọ ni. Aigbagbọ yìí niiṣe pẹlu àìní ìgboyà. Jésù
ko sọ wipe nítorípé Ọlọrun kò fẹ láti lò wọn fún iṣẹ iwosan tí wọn gbèrò láti ṣe ni. Èyí ni wipe kìíse Ọlọrun ló n
dènà de wọn. Kìíse Ọlọrun ni kò fẹ ṣeé. Ìṣòro tó n ṣẹlẹ ọdọ wọn lo wà. Ko le dá wa lójú wipe ọdọ wọn ni ìṣòro
náà wà, awọn Aposteli tí a n sọ wọnyi, Jésù ti fún ní agbára láti ṣe ìwòsàn gbogbo arun pátápátá àti gbogbo
àìsàn tí wọn lè bá pàdé nínú iṣẹ iransẹ wọn.


MATIU 10:1
[1]NIGBATI o si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀mejejila si ọdọ, o fi agbara fun wọn lori awọn ẹmi aimọ́, lati ma lé wọn
jade ati lati ṣe iwòsan gbogbo àrun ati gbogbo aisan.


Kilode ti wọn kùnà láti ṣe ìwòsàn nínú ìwé Matiu orí ketadinlogun?


MATIU 17:15-16
[15]Oluwa, ṣãnu ọmọ mi, nitori o ni warapa, o si njoro gidigidi: nigba pupọ ni ima ṣubu sinu iná, ati nigba
pupọ sinu omi.
[16]Mo si mu u tọ̀awọn ọmọ-ẹhin rẹ wá, nwọn kò si le mu u larada.

Wọn kùnà nitori aigbagbọ wọn, gẹgẹ bí Jésù ṣe ṣàlàyé ní ẹsẹ ogún. Kíni ohun tí Jésù sọ wípé yóò jẹ ọnà abayọ
kúrò nínú aigbagbọ yìí?


MATIU 17:21
[21]Ṣugbọn irú eyi ki ijade lọ bikoṣe nipa adura ati àwẹ̀.


Nítorínaa ipa tí aawẹ̀àti ádùrá náà yóò kó kìíse lórí Ọlọrun ṣugbọn lórí aigbagbọ tó wà lọkàn wọn. Aawẹ̀ati
ádùrá yóò lè aigbagbọ kúrò jáde lọkàn wọn, yóò fún wọn ní ìgboyà láti ṣe iṣẹ ìyanu.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading