Ọjọ́ Kàrún (5), Ọjọ́ Àìkú , Oṣù Kejì , Ọdún 2023

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (5)

IGBỌWỌLÈ ÀTI IṢẸ IRANSẸ (5)


Gẹgẹ bí a ti sàlàyé fún wa télètélè wípé láti ìgbà tí a bá ti gba Jésù ni Oluwa ni a ti pe wá sínú iṣẹ iransẹ. Ó ní
ipá tí àwọn ẹyà ara míràn nínú Kristi n kò láti lè jẹ kí a jẹ iṣẹ tí Olúwa pè wá sí. Ẹlòmíràn wà tí Ọlọrun yóò lo
láti pe àkíyèsí wa síi.


ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 13:1-2
[1]AWỌN woli ati awọn olukọni si mbẹ ninu ijọ ti o wà ni Antioku; Barnaba, ati Simeoni ti a npè ni Nigeri, ati
Lukiu ara Kirene, ati Manaeni, ti a tọ́pọ̀pẹlu Herodu tetrarki, ati Saulu.
[2]Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀fun mi fun
iṣẹ ti mo ti pè wọn si.


Awọn èròjà náà sì wà nípa tí Èmi tó nilo itaniji nípa iṣẹ iransẹ ẹlòmíràn.


TIMOTI KINNI 4:14
[14]Máṣe ainani ẹ̀bun ti mbẹ lara rẹ, eyiti a fi fun ọ nipa isọtẹlẹ pẹlu ifọwọle awọn àgba.


Njẹ a rí bí Paulu ṣe pe àkíyèsí Timotiu sí ònà tó gbà gba ẹbun iṣẹ iransẹ rẹ bi? Nípa igbọwọlè awọn àgba.
Awọn àgba tí Paulu n sọ níbi kíkà yìí kìíse awọn àgbàlá nípa tí ara nìkan sugbon awọn tó ti pegede nínú iṣẹ
iransẹ dé ibi wípé Ọlọrun máa n lo wọn fún igbọwọlè. Ìgbà míràn wà tó jẹ wípé àwon tí a n sọ yìí lè má ni
apele bíi Olusoaguntan tàbí Efanjelisti àti bẹẹ bẹẹ lọ. Wọn lè jẹ àwọn onígbàgbọ míràn tó ní òye nínú iṣẹ
Ọlọrun tí àwọn náà sì f’ara wọn ji daradara. Àpẹẹrẹ èyí ni Ṣaulu nígbà tó ṣẹṣẹ di onígbàgbọ nínú Kristi. Ẹni tí
Ọlọrun lo láti gb’owo lè lórí tó sì sọrọ nípa iṣẹ iransẹ rẹ kò sí lára àwọn Àpọsítélì.

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9:10-12,17
[10]Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Damasku, ti a npè ni Anania; Oluwa si wi fun u li ojuran pe, Anania. O si wipe, Wò
o, emi niyi, Oluwa.
[11]Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si lọ si ita ti a npè ni Ọgãnran, ki o si bère ẹniti a npè ni Saulu, ara Tarsu,
ni ile Juda: sá wo o, o ngbadura.
[12]On si ti ri ọkunrin kan li ojuran ti a npè ni Anania o wọle, o si fi ọwọ́le e, ki o le riran.
[17]Anania si lọ, o si wọ̀ile na; nigbati o si fi ọwọ́rẹ̀le e, o ni, Saulu Arakunrin, Oluwa li o rán mi, Jesu ti o fi
ara hàn ọ li ọ̀na ti iwọ ba wá, ki iwọ ki o le riran, ki o si kún fun Ẹmí Mimọ́.


Tí a bá ṣakiyesi, a o ri bí a ṣe ṣe àpèjúwe Ananaia, a sọ wípé ọmọ ẹhìn ni. Èyí ni wipe àpèjúwe rẹ kò yàtọ sí bí
a ṣe máa n ṣàpèjúwe ẹlòmíràn tó jẹ onígbàgbọ. Ohun tó yẹ kí a mọ nípa igbọwọlè ni wipe ìpele tí iransẹ
Ọlọrun tàbí onigbagbọ bá wà niiṣe pẹlu ẹnití o lè gb’ọwọ le tàbí ẹni tó lè gb’ọwọ lé.


HEBERU 7:7
[7]Ati li aisijiyan rara ẹniti kò to ẹni li ã sure fun lati ọdọ ẹniti o jù ni.
Ṣugbọn ohun tó yẹ kí a mọ ni wípé a kò gbọdọ sure láti gb’owo le ẹnikẹni. A gbọdọ gba awọn ènìyàn laaye
láti jẹ olotitọ sí iṣẹ Ọlọrun nípa ipè tí a pe gbogbo onigbagbọ kí a tó gb’ọwọ le wọn lori fún iṣẹ iransẹ.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading