Mọlebi & Ìgbéyàwó, Ìdàgbàsókè Nínú Kristi (6)
Ọjọ́ Kẹrinlélógún (24), Ọjọ́bọ̀ , Oṣù Kejì , Ọdún 2022
Mọlebi & Ìgbéyàwó, Ìdàgbàsókè Nínú Kristi (6)
Níwòn ìgbà tí a ti mọ wipe ifẹ Ọlọrun ni láti jẹ kí a mọ ohun tó jẹ ìfẹ rẹ nípa ọrọ ìgbéyàwó wa, báwo ni a ṣe mọ ifẹ yìí?
Ohun àkọkọ tí a gbọdọ mọ ni wipe Ọlọrun kìí tako ọrọ rẹ láéláé nítorípé nípa ẹ̀mí rẹ naa ni a fi kọ ọrọ rẹ silẹ.
TIMOTI KEJI 3:16
[16]Gbogbo iwe-mimọ́ ti o ni imísi Ọlọrun li o si ni ère fun ẹkọ́, fun ibani-wi, fun itọ́ni, fun ikọ́ni ti o wà ninu ododo:Ìmísí tàbí isipaya Ọlọrun ni a kọ sílẹ tí a n pe ní Bíbélì. Lootọ a lè má rí orúkọ ẹni tó yẹ kí a fẹ nínú Bíbélì ṣugbọn a lè mọ irú ènìyàn tí a kò gbọdọ fẹ níbẹ. Ní akọkọ igbeyawo jẹ ọkan nínú àwọn onírúurú ìbáṣepọ̀ láàrin ọmọnìyàn. Nítorinaa gbogbo irú ènìyàn tí Ọlọrun sọ nínú ọrọ rẹ wipe a kò gbọdọ ní ajọṣepọ pẹlu náà ni kò yẹ kí a ṣe ìgbéyàwó pẹlu. Ní wayi, irú àwọn wo ni Bibeli sọ wípé kò yẹ kí a ní ajọṣepọ pẹlu?
Awọn tí kò ní ìfẹ Ọlọrun lọkàn. A kò sọ wipe awọn tí kò sọ wípé àwon ní ìfẹ Ọlọrun ṣugbọn awọn tó jẹ wipe ìwà àti ìṣe wọn kò fihàn wípe wọn n rìn nínú ìfẹ Ọlọrun.
KỌRINTI KINNI 15:33
[33]Ki a má tàn nyin jẹ: ẹgbẹ́ buburu bà ìwa rere jẹ.Imọlẹ ni Bibeli pe wá, a kò gbọdọ kẹgbẹ pẹlu òkùnkùn.
EFESU 5:8
[8]Nitori ẹnyin ti jẹ òkunkun lẹ̃kan, ṣugbọn nisisiyi, ẹnyin di imọlẹ nipa ti Oluwa: ẹ mã rìn gẹgẹ bi awọn ọmọ imọlẹ:Òkùnkùn ni alaigbagbọ, Nítorinaa a kò gbà wá láàyè láti kẹgbẹ pọ pẹlú wọn pàápàá jùlọ nípa ìgbéyàwó. A ti pe wa jáde kúrò nínú okunkun.
KỌRINTI KEJI 6:15-17
[15]Irẹpọ̀ kini Kristi si ni pẹlu Beliali? tabi ipin wo li ẹniti o gbagbọ́ ni pẹlu alaigbàgbọ? [16]Irẹpọ̀ kini tẹmpili Ọlọrun si ni pẹlu oriṣa? nitori ẹnyin ni tẹmpili Ọlọrun alãye; gẹgẹ bi Ọlọrun ti wipe, Emi ó gbé inu wọn, emi o si mã rìn ninu wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi. [17]Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọ̀tọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ́ kàn ohun aimọ́; emi o si gbà nyin.Ìdí èyí ló fàá tí Pọọlù fi gba awọn ará Kọrinti ní ìmọràn wipe ẹnikẹni tó bá fẹ gbeyawo gbọdọ gbeyawo nínú Olúwa nikan. Onígbàgbọ kò le fẹ alaigbagbọ. Awọn kan tilẹ jẹ kí a mọ wipe nítorípé alaigbagbọ kìíse ọmọ Ọlọrun, èṣù ní Baba rẹ, òtítọ ni nítorípé Jésù kọ wa bẹẹ. Èyí tún túmòsi wipe onigbagbo tó bá gbeyawo pẹlu alaigbagbọ ní satani gẹgẹ bí àna rẹ nìyẹn. kò yẹ kó rí bẹẹ fún onigbagbọ rárá àti rárá.