Mọlebi & Ìgbéyàwó, Ìdàgbàsókè Nínú Kristi (4)
Ọjọ́ Kejìlélógún (22), Ọjọ́ Ìsẹ́gun , Oṣù Kejì , Ọdún 2022
Mọlebi & Ìgbéyàwó, Ìdàgbàsókè Nínú Kristi (4)
Ní àná a n sọ nípa iwẹfa, èyí ni awọn tó kọ láti gbeyawo nítorí ijoba Ọlọrun tàbí nítorí iṣẹ iransẹ. Paulu náà sọrọ nípa èyí nítorí nínú ipò yìí ni Paulu ti ṣe iṣẹ iransẹ.
KỌRINTI KINNI 7:7-8
[7]Nitori mo fẹ ki gbogbo enia ki o dabi emi tikarami. Ṣugbọn olukuluku enia ni ẹ̀bun tirẹ̀ lati ọdọ Ọlọrun wá, ọkan bi irú eyi, ati ekeji bi irú eyini. [8]Ṣugbọn mo wi fun awọn apọ́n ati opó pe, O dara fun wọn bi nwọn ba wà gẹgẹ bi emi ti wà.Awọn olukọ Bíbélì kan máa n sọ wípé Paaulu kò fẹ kí àwọn ènìyàn gbé ìyàwó ni. Kìíse bẹẹ rárá. Paaulu sọ wípé òun ní ẹtọ láti gbeyawo gẹgẹ bí àwọn Aposteli yòókù náà ti gbeyawo ṣugbọn nínú ohun tí Paulu rí gẹgẹbi agbelebu tirẹ ni láti kọ ẹtọ náà silẹ. Nitorinaa kìíse ẹkọ fún òjíṣẹ Ọlọrun bikòṣe ohun tí Paulu yàn gẹgẹ bí Aposteli.
KỌRINTI KINNI 9:4-5
[4]Awa kò ha li agbara lati mã jẹ ati lati mã mu? [5]Awa kò ha li agbara lati mã mu aya ti iṣe arabinrin kiri, gẹgẹ bi awọn Aposteli miran, ati bi awọn arakunrin Oluwa, ati Kefa?Ìdí èyí ni a ti n mọ iransẹ Ọlọrun tòótọ. Kìíse gbogbo ohun tí a lẹtọ láti ṣe ni a gbọdọ ṣe, igba míràn wà tí a ní láti kọ àwọn ẹtọ wa silẹ nitori kí a lè rí ààyè ṣe iṣẹ Ọlọrun. Pétérù ní ìyàwó, sibẹsibẹ, Jésù lò fún iṣẹ iransẹ.
LUKU 4:38
[38]Nigbati o si dide kuro ninu sinagogu, o si wọ̀ ile Simoni lọ; ibà si ti dá iya aya Simoni bulẹ; nwọn si bẹ̀ ẹ nitori rẹ̀.Ìdáhùn míràn tí tun lè fún àwọn tó sọ wípé Pọọlù kò fẹ kí a gbeyawo ni wipe “nje a tilẹ rántí wípé Pọọlù yìí kan náà ló kọ lẹta sí Timotiu ọmọlẹyìn rẹ nípa àwọn tí a bá fẹ Yàn láti ṣe adari nínú ìjọ Ọlọrun.
TIMOTI KINNI 3:1-2
[1]OTITỌ ni ọ̀rọ na, bi ẹnikan ba fẹ oyè biṣopu, iṣẹ rere li o nfẹ. [2]Njẹ biṣopu jẹ alailẹgan, ọkọ aya kan, oluṣọra, alairekọja, oniwa yiyẹ, olufẹ alejò ṣiṣe, ẹniti o le ṣe olukọ.Njẹ a ri wipe Pọọlù sọ wípé o yẹ kí Bisopu jẹ ọkọ aya kan? Nitorinaa a kò le sọ wípé Pọọlù kò fẹ kí onigbagbọ tàbí iransẹ Ọlọrun gbeyawo.
Kókó ẹkọ rẹ ni ni wipe ẹnikẹni tó bá gbeyawo gbọdọ sìn Ọlọrun gẹgẹ bíi ìgbà wipe ko gbeyawo. Ẹnikẹ́ni tí kò bá tíì gbeyawo náà gbọdọ mú iṣẹ Ọlọrun gẹgẹ bíi ohun tó ṣe pàtàkì.
KỌRINTI KINNI 7:29
[29]Ṣugbọn eyi ni mo wi, ará, pe kukuru li akokò: lati isisiyi lọ pe ki awọn ti o li aya ki o dabi ẹnipe nwọn kò ni rí;