Mọlebi & Ìgbéyàwó, Ìdàgbàsókè Nínú Kristi (2)
Ọjọ́ Ogún (20), Ọjọ́ Àìkú , Oṣù Kejì , Ọdún 2022
Mọlebi & Ìgbéyàwó, Ìdàgbàsókè Nínú Kristi (2)
Ní àna a ti jẹ kí a mọ wipe ipa ti ọrọ Ọlọrun n ko nínú ayé onigbagbọ se pàtàkì lọpọlọpọ. Ọkan ninu ibi tí onigbagbọ ti lè dúró sínsisn nínú ìfẹ Ọlọrun ni nínú ọrọ nípa mọlẹbi. Ọrọ mọlẹbi, ìgbéyàwó àti bẹẹ bẹẹ lọ ṣe pàtàkì dé ibi wipe Ọlọrun náà ní àwon ìlànà tó yẹ kí a tẹlẹ lórí ọrọ náà. Igbesiaye Kristẹni lè sòrò fún ọpọlọpọ nítorí ìyàwó tàbí ọkọ tí wọn fẹ ni igba míràn.
Lootọ orukọ ẹni tó yẹ kí Kristẹni fẹ gẹgẹ bí ìyàwó tàbí ọrọ kò sí nínú Bíbélì ṣugbọn awọn ìlànà kan wà tí a lè tẹlẹ. Nínú irú ohun tí a nsọ yìí, ọpọlọpọ onígbàgbọ tàbí àwọn iransẹ Ọlọrun máa n ṣe aṣiṣe láti lo ọgbọn orí ara wọn tàbí ìrírí ayé láti gba àwọn onígbàgbọ ní àmọ̀ràn, kò yẹ kó rí bẹẹ rárá. Gẹgẹ bí a ti sàlàyé lánàá, ohunkóhun tí Bíbélì bá ti ní ìlànà lórí rẹ, a kò gbọdọ máa lo ọgbọn orí ara wa láti ṣeé.
Èkíní nínú ohun tí a fẹ mẹnuba nínú ẹkọ nípa ohùn tí ọrọ Ọlọrun sọ fún wa nípa ìgbéyàwó ni wipe láàrin ọkunrin àti obìnrin ni.
JẸNẸSISI 2:24
[24]Nitori na li ọkunrin yio ṣe ma fi baba on iya rẹ̀ silẹ, yio si fi ara mọ́ aya rẹ̀: nwọn o si di ara kan.Ọlọrun fi ìlànà yìí sílè lati ibẹrẹ. Ní ìgbà atijọ, a lè má nilo láti ràn ara wa létí èyí ṣugbọn kò rí bẹẹ mọ nisisiyi. Ni ibi tí ayé dé dúró lóde òní, a gbọdọ ran ara wa létí wipe ọkunrin àti obìnrin ni Ọlọrun fọwọsi kìíse takọtakọ tàbí tabotabo rárá. Ohun tí Mósè kọ nínú ìwé Jenesisi yìí náà jẹ́ ohun tí Jésu náà ṣe atilẹyin fún ninu ẹkọ rẹ.
MATIU 19:4-5
[4]O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ko ti kà a pe, ẹniti o dá wọn nigba àtetekọṣe o da wọn ti akọ ti abo, [5]O si wipe, Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, yio famọ́ aya rẹ̀; awọn mejeji a si di ara kan.Kò sí ìbi kankan ti Ọlọrun ti fi ìbùkún ìgbéyàwó sí ibaṣepọ tó yàtọ sí láàrin ọkunrin àti obìnrin. Njẹ ni iwọn ìgbàtí a ti sọ èyí, ó yẹ láti máa ṣe idajọ awọn tí wọn tapa sí èyí?
Ohun tí a gbọdọ mọ gẹgẹ bí onigbagbọ ni wipe ìlànà Ọlọrun wà fún àwa ọmọ rẹ nikan ni.
HEBERU 12:6
[6]Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ, on ni ibawi, a si mã nà olukuluku ọmọ ti o gbà.Àwa ni a ní ojúṣe láti tẹlé ọrọ Ọlọrun kìíse alaigbagbọ. Iṣẹ kàn tàbí ìlànà kan péré tí Ọlọrun ní fún alaigbagbọ ni láti gbàgbọ́ nínú ìhìnrere Kristi. Nitorinaa ohun tí a n sọ ni wipe ènìyàn tó bá sọ wípé Kristẹni ni ohun tàbí atunbi, a kò gbọdọ sọ gẹgẹ bí àwọn ọmọ ayé ti yìí wipe ko sí ohun tó burú nípa takọtakọ tàbí tabotabo. Irú nkan bẹẹ, ẹsẹ ni Bíbélì pèé.
ROMU 1:27-28 [27]
Gẹgẹ bẹ̃ li awọn ọkunrin pẹlu, nwọn a mã fi ilò obinrin nipa ti ẹda silẹ, nwọn a mã ni ifẹkufẹ gbigbona si ara wọn; ọkunrin mba ọkunrin ṣe eyi ti kò yẹ, nwọn si njẹ ère ìṣina wọn ninu ara wọn bi o ti yẹ si. [28]Ati gẹgẹ bi nwọn ti kọ̀ lati ni ìro Ọlọrun ni ìmọ wọn, Ọlọrun fi wọn fun iyè rirà lati ṣe ohun ti kò tọ́: