Mọlebi & Ìgbéyàwó, Ìdàgbàsókè Nínú Kristi (10)
Ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n (28), Ọjọ́ Ajé , Oṣù Kejì , Ọdún 2022
Mọlebi & Ìgbéyàwó, Ìdàgbàsókè Nínú Kristi (10)
Tí a kò bá pinnu láti máa fojú fo awọn aleebu tí ẹnikọọkan ní, bí ija bí ilara ni yóò máa wọpọ nínú ilé tàbí mọlebi wa lootọ lootọ Kristẹni ni a jẹ. Àṣírí irẹpọ láàrin tọkọtaya onigbagbọ ni wípé kí ẹnikọọkan pinnu wipe bó tilẹ jẹ wípé ẹnìkejì lè má ṣe irú ìpinnu bẹẹ, ṣugbọn kí enìkan pinnu wipe òun yóò máa rìn nínú imọlẹ ọrọ Ọlọrun. Tí a bá n rìn nínú ohùn tí Bíbélì se àpèjúwe gẹgẹ bí ìfẹ ti Kristi, yóò sòrò fún edeaiyede láti máa jọba nínú ilé wa gẹgẹ bíi Kristẹni.
Ẹ jẹ kí a ṣàlàyé diẹ nipa bí bíbélì ṣe gba wá ní ìmọràn láti máa rìn nínú ìfẹ ní gbogbo ìgbà.
KỌRINTI KINNI 13:4
[4]Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun; ifẹ kì iṣe ilara; ifẹ kì isọrọ igberaga, kì ifẹ̀,Ìfẹ máa n mú sùúrù. Ọpọlọpọ edeaiyede laarin lokolaya niiṣe pẹlu aile ní sùúrù fún ara ẹni. Tí a bá n mú sùúrù, awọn ìwà kan wà tó jẹ wípé wọn kò ní ní ipá lórí ọkàn wa. Sùúrù ni yóò fi gba wa láàyè láti rántí ọrọ Kristi. Sùúrù ni yóò ma jẹ kí a lè gbọ ara ẹni yé. Nítorinaa sùúrù yí ṣe pàtàkì. Sugbon ninu gbogbo awọn ìwà ìrẹlẹ yìí, ohun tó jẹ kí onigbagbọ yatọ sí alaigbagbọ ni wipe awọn ìwà yìí wà lára wa gẹgẹ bí ẹni tó ti di àtúnbí. Nítorípé nínú àtúnbí, Ọlọrun ni baba wa, bẹẹ náà sì ni iseda Ọlọrun jẹ iseda wa nínú Kristi.
PETERU KINNI 1:23
[23]Bi a ti tun nyin bi, kì iṣe lati inu irú ti idibajẹ wá, bikoṣe eyiti ki idibajẹ, nipa ọ̀rọ Ọlọrun ti mbẹ lãye ti o si duro.Ọlọrun ló tún wa bi. A ti di ẹda títún nínú rẹ. Èyí túmò sí wipe a ti ní iseda ọtun.
KỌRINTI KEJI 5:17-18
[17]Nitorina bi ẹnikẹni ba wà ninu Kristi, o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi I, nwọn si di titun. [18]Ohun gbogbo si ti ọdọ Ọlọrun wá, ẹniti o si ti ipasẹ Jesu Kristi ba wa laja sọdọ ara rẹ̀, ti o si ti fi iṣẹ-iranṣẹ ìlaja fun wa;Nítorinaa awọn iwa-bi-olorun ti jẹ ara iseda wa gẹgẹ bí onigbagbọ. Ọkan nínú àwọn ìwà bí Ọlọrun yìí ni sùúrù.
PETERU KEJI 3:9
[9]Oluwa kò fi ileri rẹ̀ jafara, bi awọn ẹlomiran ti ikà a si ijafara; ṣugbọn o nmu sũru fun nyin nitori kò fẹ ki ẹnikẹni ki o ṣegbé, bikoṣe ki gbogbo enia ki o wá si ironupiwada.Nítorípé Ọlọrun n mú sùúrù fún wa. Ojúṣe wa ni kí àwa náà máa mú sùúrù fún ọmọnikeji náà, pàápàá jùlọ nínú mọlebi wà, láàárín ọkọ àti aya. Ọnà tí a lè gbà kí iseda yìí máa farahàn nígbà gbogbo nínú ayé wa náà ni kí a máa rántí ní gbogbo ìgbà wípé a ti di ẹda títún. Báwo ni a ṣe lè máa rántí èyí ní gbogbo ìgbà bikòṣe kí ọkàn wa kún fún ọrọ Ọlọrun nípa àṣàrò nínú ọrọ rẹ, kí a wẹ ọkan wa mọ kúrò nínú bí àwọn ọmọ ti ayé yìí ṣe máa n ronú
ROMU 12:2
[2]Ki ẹ má si da ara nyin pọ̀ mọ́ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin, ki ẹnyin ki o le ri idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara, ti o si ṣe itẹwọgbà, ti o si pé.