Mọlebi & Ìgbéyàwó, Ìdàgbàsókè Nínú Kristi (1)
Ọjọ́ Kọkàndínlógún (19), Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Oṣù Kejì , Ọdún 2022
Mọlebi & Ìgbéyàwó, Ìdàgbàsókè Nínú Kristi (1)
Ìgbà míràn wà tó jẹ wipe a máa n gba awọn eniyan láàyè lati kọ wa ní ohun tó jẹ wipe Bibeli ko dakẹ jẹ nípa rẹ. Gẹgẹ bíi Kristẹni tòótọ ohunkóhun tí Bíbélì bá sọ nípa ohun kan tàbí òmíràn ló jẹ ohun tí Ọlọrun ní lọkàn nípa nkan náà. Nitorinaa ti a ba fẹ lati mọ ohùn tí Ọlọrun ní lérò nípa nkan kàn, inú Bíbélì ni a ó ti wo imọran tí Ọlọrun fún wa nípa rẹ.
A fi ọrọ Ọlọrun fún onigbagbọ ninu Kristi láti ṣe amọna fún wa ni.
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 20:32
[32]Njẹ nisisiyi, ará, mo fi nyin le Ọlọrun lọwọ ati ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, ti o le gbe nyin duro, ti o si le fun nyin ni ini lãrin gbogbo awọn ti a sọ di mimọ́.Nínú ibi tí a kà yìí, Paulu n fi wọn lé ọrọ Ọlọrun lọwọ nitoripe o mọ wipe nipasẹ ọrọ náà ni a fi lè gbé wọn ró. Nipasẹ ọrọ náà ni wọn yóò ṣe dagbasoke. Kò tó di igbayii gab ni a ti rí iru ìlànà yìí nínú Bíbélì. Gbogbo ẹnikẹ́ni tó bá fẹ bá Ọlọrun rìn gbọdọ nifẹ sí gbigbọ tàbí ṣiṣe àṣàrò nínú ọrọ rẹ.
ORIN DAFIDI 119:11
[11]Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ.Njẹ a ri àṣírí Dafidi bayii? Nípa ọrọ Ọlọrun ló ṣe n bá Ọlọrun rìn. Ìgbọràn sí Ọrọ Ọlọrun ṣe pàtàkì lootọ ṣugbọn kò sí bí a ṣe fẹ gbọran sí ohùn tí a kò mọ. Ìdí èyí ló ṣe ṣe pàtàkì láti mọ ọrọ Ọlọrun. Ẹni tó mọ ọrọ náà tí kò ṣeé àti ẹni tí kò nifẹ sí ọrọ naa, alaigbọran ni awọn méjèèjì.
Ìdí èyí ni a se pe Dafidi ní ẹni bí ọkan Ọlọrun. Ẹnikẹ́ni tó bá ti mọ ọrọ Ọlọrun ti mọ ohùn tí Ọlọrun ní lọkàn nìyẹn tí nítorípé Ọlọrun kìíse èké, ohunkóhun tí a bá tí rí nínú ọrọ rẹ jẹ ìfẹ rẹ, o sì jasi wipe ohun tí Ọlọrun ní lọkàn náà nìyẹn.
ÌWÉ ÒWE 4:20-23
[20]Ọmọ mi, fetisi ọ̀rọ mi; dẹti rẹ silẹ si ọ̀rọ mi. [21]Máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ; pa wọn mọ́ li ãrin aiya rẹ. [22]Nitori ìye ni nwọn iṣe fun awọn ti o wá wọn ri, ati imularada si gbogbo ẹran-ara wọn. [23]Jù gbogbo ohun ipamọ́, pa aiya rẹ mọ́; nitoripe lati inu rẹ̀ wá ni orisun ìye.Kìíse ipá kekere ni ọrọ Ọlọrun n ko nínú ayé onigbagbọ. . Mósè náà sọ eyi fún Jóṣúà.
JOṢUA 1:8
[8]Iwé ofin yi kò gbọdọ kuro li ẹnu rẹ, ṣugbọn iwọ o ma ṣe àṣaro ninu rẹ̀ li ọsán ati li oru, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu rẹ̀: nitori nigbana ni iwọ o ṣe ọ̀na rẹ ni rere, nigbana ni yio si dara fun ọ.