Kí Ló N Ṣe Fún Ọlọrun? (4)
Ọjọ́ Kẹjọ (8), Ọjọ́ Ìsẹ́gun , Oṣù Kejì , Ọdún 2022 Kí Ló N Ṣe Fún Ọlọrun? (4) Ansọrọ nípa riran awọn iransẹ Ọlọrun lọwọ. Nínú iṣẹ iransẹ Jésù, awọn kan wà tí wọn máa n ṣe iranlọwọ fún Oluwa wa. LUKU 8:1-3 [1]O si ṣe lẹhinna, ti o nlà gbogbo ilu ati iletò lọ, o nwasu, o nrò ìhin ayọ̀ ijọba Ọlọrun: awọn mejila si mbẹ lọdọ rẹ̀. [2]Ati awọn obinrin kan, ti a ti mu larada kuro lọwọ awọn ẹmi buburu, ati ninu ailera wọn, Maria ti a npè ni Magdalene, lara ẹniti ẹmi èṣu meje ti jade kuro, [3]Ati Joanna aya Kusa ti iṣe iriju Herodu, ati Susanna, ati awọn pipọ miran, ti nwọn nṣe iranṣẹ fun u ninu ohun ini wọn. Bíbélì sọ fún wa nínú àbala tí a tọkasi yìí wipe awọn obinrin yìí máa n ṣe iransẹ fún Kristi lára ohun ìní wọn. Èyí n sọ fún wa wípé o lè jẹ owó, tàbí láti inú dukiya wọn ni wọn ti máa n ṣe atilẹyin fún Kristi. Njẹ a mọ wipe ẹnikẹni tó bá ṣe atilẹyin fún àwọn iransẹ Ọlọrun pẹlu ìgbàgbọ ki yóò pàdánù èrè rẹ? Ìdí rẹ ni wipe awọn tí a n ti lẹhin yìí n ṣe ohun gbogbo tí wọn ṣe lórúko Kristi ni. MATIU 10:42 [42]Ẹnikẹni ti o ba fi kìki ago omi tutù fun ọkan ninu awọn onirẹlẹ wọnyi mu nitori orukọ ọmọ-ẹhin, lõtọ ni mo wi fun nyin, kì o padanù ère rẹ̀. Awọn tó n ṣe ibi fún àwọn iransẹ Ọlọrun náà, Njẹ a mọ wipe Kristi ni wọn n ṣee sí? Ìgbà kan wà tó jẹ wípé Pọọlù Aposteli wà lára àwọn tó n ṣe inúnibíni sí àwọn onígbàgbọ nínú Kristi. ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 7:58 [58]Nwọn si wọ́ ọ sẹhin ode ilu, nwọn sọ ọ lí okuta: awọn ẹlẹri si fi aṣọ wọn lelẹ li ẹsẹ ọmọkunrin kan ti a npè ni Saulu. Ṣugbọn nígbà tó bá Jésù pàdé ẹ gbọ ohun tí Jésù sọ fún. ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9:5 [5]O si wipe, Iwọ tani, Oluwa? Oluwa si wipe, Emi Jesu ni, ẹniti iwọ nṣe inunibini si: ohun irora ni fun ọ lati tapá si ẹgún. Jésù sọ fún Pọọlù wipe òun ni ẹni tí Pọọlù n ṣe inúnibíni sí, ṣugbọn iyalẹnu ni èyí jẹ nítorípé Pọọlù kò bá Jésù pàdé nípa ti ara rí. Báwo wá ní Pọọlù ṣe ṣe inúnibíni sí Jésù? Àlàyé rẹ ni wipe ohunkóhun tí a bá ṣe sí àwọn iransẹ Ọlọrun, ojú tí Jésù fi n wòó ni wípé òun gan ni a ṣe nkán náà sí. Nitorinà ohunkóhun tí a bá fún wọn láti ràn wọn lọwọ nínú iṣẹ ìhìnrere tàbí láti lò fún ara wọn, Jésù máa fojú wòó bí ìgbà wípé òun gán ni a fún ní nkan náà. Awọn ijọ Ọlọrun tó wà ní Filippi náà ṣe irú atilẹyin yi fún Pọọlù. FILIPI 4:14,16 [14]Ṣugbọn ẹnyin ṣeun gidigidi niti pe ẹnyin ṣe alabapin ninu ipọnju mi. [16]Nitori ni Tessalonika gidi, ẹnyin ranṣẹ, […]
Read More