Lilo Ẹbùn Èmi Mimọ (7)
Ọjọ́ Kejìdínlógún (18), Ọjọ́ Ẹtì , Oṣù Kejì , Ọdún 2022 Lilo Ẹbùn Èmi Mimọ (7) Ìbí tó ti yẹ kí ènìyàn ṣọra lọpọlọpọ ni wípé o ṣeéṣe kí agbára Ọlọrun máa farahàn ṣugbọn kí ìfẹ Ọlọrun má jẹyọ níbẹ, bẹẹ ni. Nígbàtí orugbẹ n gbẹ awọn ọmọ Israẹli, ohun tí wọn kà sí iṣẹ ìyanu ni kí omi farahàn. Ẹnikẹni tí orugbẹ n gbẹ, omi nìkan ni iṣẹ ìyanu tó lè yé irú ènìyàn bẹẹ. Bẹẹ ló rí fún àwọn ọmọ Israẹli nínú aginjù nítorípé orugbẹ n gbẹ wọn gidigidi wọn sì ke sí Mósè. Nítorinaa tí ìpèsè omi mímu bá ti wa, awọn ti gbagbọ wípé ìfẹ Ọlọrun ti farahàn nìyẹn. NỌMBA 20:9-13 [9]Mose si mú ọpá na lati iwaju OLUWA lọ, bi o ti fun u li aṣẹ. [10]Mose ati Aaroni si pe ijọ awọn enia jọ niwaju apata na, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin gbọ̀ nisisiyi, ẹnyin ọlọtẹ; ki awa ki o ha mú omi lati inu apata yi fun nyin wá bi? [11]Mose si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o si fi ọpá rẹ̀ lù apata na lẹ̃meji: omi si tú jade li ọ̀pọlọpọ, ijọ awọn enia si mu, ati ẹran wọn pẹlu. [12]OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Nitoriti ẹnyin kò gbà mi gbọ́, lati yà mi simimọ́ loju awọn ọmọ Israeli, nitorina ẹnyin ki yio mú ijọ awọn enia yi lọ si ilẹ na ti mo fi fun wọn. [13]Wọnyi li omi Meriba; nitoriti awọn ọmọ Israeli bá OLUWA sọ̀, o si di ẹni ìya-simimọ́ ninu wọn. Kìíṣe ìbínú ló fàá tí Mósè kò wọ ilẹ ìlérí ṣugbọn nítorípé kò dúró ṣinṣin nínú ìfẹ Ọlọrun. Gbogbo ohun tí Mósè àti àwọn wòlíì yòókù n sọ nígbà náà niiṣe pẹlu ìgbàlà tó wà nínú Kristi ti yóò wáyé. Nítorinaa, àpáta tí Mósè fi ọpa lu náà ṣe àpẹẹrẹ Kristi. KỌRINTI KINNI 10:4 [4]Ti gbogbo wọn si mu ohun mimu ẹmí kanna: nitoripe nwọn nmu ninu Apata ẹmí ti ntọ̀ wọn lẹhin: Kristi si li Apata na. Nitorinà bí Mósè ti lu àpáta náà n ṣàpèjúwe bí a o ti na Kristi fún aiṣedede wa tí kò omi ìyè yóò sì jáde nipasẹ eyi fún gbogbo ènìyàn. JOHANU 4:14 [14]Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orùngbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rẹ̀, ti yio ma sun si ìye ainipẹkun. Nitorinà lílu tí Mósè lu àpáta náà n ṣàpèjúwe bí Jésù yóò ṣe kú tí àwa yóò sì ní ìyè nipa ikú àti àjínde rẹ. Báwo ni Mósè ṣe tapa sí ìpinnu Ọlọrun nínú èyí? HEBERU 10:14 […]
Read More