Ọjọ́ Kíní (1), Ọjọ́ Àìkú , Oṣù Kíní , Ọdún 2023

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(1)

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ WA NIPA AAWẸ̀(1)

Gẹgẹ bí onigbagbọ, Jésù ní a máa fi n ṣe awokọṣe. Nítorínaa tí a bá n sọrọ nípa aawẹ̀àti ádùrá, Ọ yẹ kí a ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ nínú igbesiaye ati ẹkọ tí Jésù Olúwa wa gan kọ́nípa rẹ. A rí wípé lootọ ni Jésù Olúwa gan gba
aawẹ nínú iṣẹ iransẹ rẹ, pàápàá jùlọ ko tó bẹrẹ iṣẹ iransẹ rẹ, O gba awẹ.

MATIU 4:1-2
[1]NIGBANA li a dari Jesu si ijù lati ọwọ́Ẹmi lati dán a wò lọwọ Èṣu.
[2]Nigbati o si ti gbàwẹ li ogoji ọsán ati ogoji oru, lẹhinna ni ebi npa a.

Ní iwọn ìgbà tó jẹ wípé Jésù gba awẹ, a jẹ wípé àwa náà gẹgẹ bí ẹni tó wà ní ipò ọmọlẹyìn láyé òde òni gbọdọ
tẹle ipasẹ rẹ nìyẹn. Nítorínaa, aawẹ kò ní bóyá tabi ṣugbọn nínú fún onigbagbọ, ohun tí Ọlọrun retí wípé a o
máa ṣe gẹgẹ bí àmin ifara-eni-jin fún iṣẹ rẹ ni.


Àkíyèsí pàtàkì nínú bí Jésù Olúwa ṣe gbawẹ ni wipe Jesu kò gbawẹ nitoripe ogun ayé n lè káàkiri kìíse nitope
èṣù lágbára. Ìdí tí Jésù fi gba awẹ ni wipe o fara rẹ jìn fún ìfẹ Ọlọrun ni. A o rí nínú àbala tí a tọkasi yìí wipe
Èmi Mimọ ló darí rẹ láti gba awẹ. Nítorínáà gẹgẹ bí Onigbagbọ, o t’ọna láti gba awẹ ṣugbọn a gbọdọ fi
iwọntunwọnsi sí gbogbo nkan.


Njẹ a tilẹ ṣakiyesi wipe ẹẹkan péré tí a tọkasi Aawẹ̀nínú iṣẹ iransẹ Jésù ni èyí? Nítorínáà kìíse wipe gbogbo
igba ni Jésù máa n gba Aawẹ̀. A kò gbọdọ̀fi ìlera wa we ewu nítorípé kí Ọlọrun tó lè lò wá fún iṣẹ rẹ ní ayé yìí,
a nilo láti wà nínú ara. Tí ẹ̀mí kò bá sí, kò sí ohunkóhun tó n jẹ iṣẹ iransẹ. Nítorínáà, ojúṣe wa ni gẹgẹ bí
Kristẹni ki ìlera ara wa jẹ wá lógún

Sibẹsibẹ Jésù fún wa ni awọn Ilana tó yẹ kí a tẹle láti lè gbawẹ ní ọnà tó bá ìfẹ Ọlọrun mu.


MATIU 6:16-18
[16]Ati pẹlu nigbati ẹnyin ba ngbàwẹ, ẹ máṣe dabi awọn agabagebe ti nfajuro; nwọn a ba oju jẹ, nitori ki
nwọn ki o ba le farahàn fun enia pe nwọn ngbàwẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na.
[17]Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbàwẹ, fi oróro kùn ori rẹ, ki o si bọju rẹ;
[18]Ki iwọ ki o máṣe farahàn fun enia pe iwọ ngbàwẹ, bikoṣe fun Baba rẹ ti o mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si
riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba.


Jésù n sọ fún wa kí a má ṣe dàbí awọn àgabagebe. Kìíse ohun tí àwọn agabagebe ṣe gan ló ṣe pàtàkì jùlọ
bikòṣe nítorí ohun tí wọn ṣe n ṣeé gan. Wọn máa n ṣe awọn iṣẹ ìsìn láti lè jẹ kí àwọn ènìyàn mọ wipe lootọ ni
wọn n sin Ọlọrun, èyí ni wípé wọn fẹ kí àwọn ènìyàn máa bu ọlá fún wọn. Irú awẹ bẹẹ kò ní itẹwọgba lọdọ
Ọlọrun.

No comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Loading