Eko Bibeli Ni Ede Yoruba.

Ẹ Káàbọ̀

Ẹ káàbò sí Ìdánilẹ́ko Bíbélì. Inú wa dùn wípé ẹ ti ṣetan lati mú ẹkọ ọrọ Ọlọrun ní okunkundun. Gẹgẹ bí
onigbagbọ, kò ṣeeṣe lati dagbasoke àyàfi nípa ṣíṣe àṣàrò àti ẹkọ ninu ọrọ Ọlọrun. Nitorina, ìgbésẹ tí ẹ gbé yìí láti wá ṣe ayẹwo website wa yi ṣe pàtàkì gidigidi gan ni.

Pẹlu ádùrá ni a fi ṣe agbekalẹ awọn ẹkọ tó wà lórí website yìí, nitorina ádùrá wa ji wípé Ọlọrun yóò fún
yín ní ọgbọn, ìmọ àti òye láti lè ní ìfihàn nínú ọrọ rẹ àti oore-ọfẹ láti lè kọ àwọn ẹlòmíràn náà pẹlu.

Tí Ọlọrun bá ti lo awọn ẹkọ yìí láti gbé yin ro nínú ìgbàgbọ àti lati bukun yin, ẹ jọwọ e b’awa sọ fún àwọn
míràn náà kí wọn lè ní anfààní láti gba ìbùkún tí ẹyin náà ti rí gbà.

Ẹ ṣeun púpọ. Jésù ní Olúwa.

Loading